1 Asiwèrè wí ní ọkàn Rẹ̀ pé:“Ọlọ́run kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;kò sì sí ẹnìkan tí ń ṣe rere.
2 Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀runsórí àwọn ọmọ ènìyànláti wò bóyá ẹnìkan wà tí ó ní òye,tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
3 Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
4 Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹuntí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
5 Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńláníbì tí ẹ̀rù kò gbé sínítorí Ọlọ́rún tí fọ́n egungun àwọn tí ó dótì ọ́ ká;ìwọ tí dójú tì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.
6 Ìgbàlà Ísírẹ́lì ìbá jáde wá láti Síónì!Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà,jẹ́ kí Jákọ́bù yọ̀ kí inú Ísírẹ́lì sì máa dùn!