1 Olúwa, Ta ni yóò máa gbé nínú àgọ́ mímọ́ Rẹ?Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ Rẹ?
2 Ẹni tí ń rìn déédéétí ó sì ń sọ òtítọ́,láti inú ọkàn Rẹ̀
3 tí kò fi ahọ́n Rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò Rẹ̀tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì Rẹ̀,
4 ní ojú ẹni tí ènìyàn-kénìyàn di gígànṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,Ẹni tí ó búra sí ibi ara Rẹ̀àní tí kò sì yípadà,
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlékò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyíni a kì yóò mì láéláé.