1 Ìwọ tí kọ̀ wá sílẹ̀,Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa káìwọ ti bínú nísìnsín yìí, tún ara Rẹ yípadà sí wá.
2 Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;mú fífọ́ Rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mi.
3 Ìwọ ti fi ìgbà ewu hàn àwọn ènìyàn Rẹ;Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wa gbọ́n-ọ́ngbọ́n-ọ́n.
4 Àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ní ìwọ fi ọ̀págun fúnkí a lè fíhàn nítorí òtítọ́. Sela
5 Fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́,kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ Rẹ̀:“Ní ayọ̀, èmi ó pín ṣèkémù jádeèmi o sì wọ̀n àfonífojì ṣúkótù.
7 Tèmi ni Gílíádì, tèmi sì ni Mánásè;Éfúráímù ni àsìbórì mi,Júdà sì ní ọ̀pá àṣẹ mi.
8 Móábù ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,lórí Édómù ní mo bọ́ bàtà mi sí;lórí fìlísitinì ni mo kígbe ayọ̀.”
9 Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Édómù?
10 Kí ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,nítorí asán ní ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a ó ní ìṣẹ́gun,yóò sì tẹ̀ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.