1 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,ó sì dámi lóhùn
2 Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ète èkéàti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3 Kí ni kí a fi fún ọ?Àti kín kí a tún ṣe fún ọ,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4 Òun yóò bá ọ́ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,pẹ̀lú eyin iná igi ìgbálẹ̀.
5 Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Mésékì,nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kédárì!
6 Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbéláàrin àwọn tí ó kóríra àlàáfíà.
7 Ènìyàn àlàáfíà ni mí;ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni ti wọn.