Sáàmù 69 BMY

Àdúrà Fún Ìdáǹde Lọ́wọ́ Ọ̀ta

1 Gbàmí, Ọlọ́run,nítorí omi tí kún dé ọrùn mi.

2 Mo ń rì nínú ìrà jínjìn,níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.Mo ti wá sínú omi jínjìn;ìkún omi bò mí mólẹ̀.

3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,nígbà ti èmi dúró de Ọlọ́run mi

4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìíwọn ju irun orí mi; lọpúpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,àwọn tí ń wá láti pa mí runA fi ipá mú miláti san ohun tí èmi kò jí.

5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú Rẹ.

6 Má ṣe dójú tì àwọn tí ó ní ìrètí nínú Rẹnítorí mi, Olúwa, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7 Nítorí Rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,ìtìjú sì bo ojú mi.

8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

9 Nítorí ìtarà ilé Rẹ jẹ mí run,àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10 Nígbà tí mo sunkúntí mo sì ń fi ààwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyàèyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11 Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,àwọn ènìyàn ń pòwe mọ́ mi.

12 Àwọn tí ó jòkòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi niìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí Olúwa,ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbàỌlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ,dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú.

14 Gbá mí kúrò nínú ẹrẹ̀,Má ṣe jẹ́ kí ń rí;gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí o korìíra mi,kúrò nínú ibú omi.

15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mìkí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu Rẹ̀ dé mọ́ mi.

16 Dá mí lóhùn, Olúwa nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ;nínú ọ̀pọ̀ àánú Rẹ yípadà sí mi.

17 Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ:yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18 Súnmọ́ tòsí kí ó sì gbà mí là;rà mí padà nítorí àwọn ọ̀ta mi.

19 Ìwọ tí mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;Gbogbo àwọn ọ̀ta mi wà níwájú Rẹ̀.

20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,àti ní òungbẹ mi, wọn fi ọtí kíkan fún mi.

22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùnni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹfún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23 Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran,kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé.

24 Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn;kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25 Kí ibùjókòó wọn di ahoro;kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe

27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà Rẹ.

28 Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyèkí á má kà wọn pẹ̀lú àwọn olódodo.

29 Ṣùgbọ́n talákà àti ẹni-ìkáánú ni èmí,Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà Rẹ gbé mi lékè.

30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run gaèmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga.

31 Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.

32 Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀:Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè!

33 Olúwa, gbọ́ ti aláìníkí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀,

35 Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Síónì làyóò sì tún àwọn ìlú Júdà wọ̀nyí kọ́.Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,kí wọn ó lè máa níi ni ilẹ̀ ìní

36 Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún Rẹ̀,àwọn ti ó fẹ́ orúkọ Rẹ ní yóò máa gbé inú Rẹ̀.