1 Kí Olúwa kí ó gbóhùn Rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú;kí orúkọ Ọlọ́run Jákọ́bù kí ó dáàbòbò ọ́.
2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Síónì wá.
3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ ọrẹ Rẹkí ó sì gba ẹbọ sísun un Rẹ. Sela
4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn Rẹkí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ Rẹ ṣẹ.
5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gunàwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè Rẹ̀ ṣẹ.
6 Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé Olúwa pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́;yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wápẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọn sì ṣubú,ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!