1 Olúwa jọba, jẹ́ kí ayé kí o yọ̀jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn
2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yí káòdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ Rẹ̀.
3 Iná ń jó níwájú Rẹ̀. O sì ń jó àwọn ọ̀ta Rẹ̀ yíká kiri
4 Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn ó sí kárí ayéayé rí i ó sì wárìrì
5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo Rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo Rẹ̀.
7 Gbogbo àwọn tí ń sin òrìṣà ni ojú yóò ti,àwọn ti n fi ère ṣe àfẹ́rí ara wọnẸsìn ín, ẹ̀yin òrìṣà;
8 Síónì gbọ́, inú Rẹ̀ sì dùnìnú àwọn ilé Júdà sì dùnNítorí ìdájọ́ Rẹ, Olúwa
9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ní ó ga ju gbogbo ayé lọìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìsà lọ.
10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórira ibi, ó pa ọkan àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ mọ́ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodoàti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn
12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,kí ẹ sì yin orúkọ Rẹ̀ mímọ́.