Sáàmù 119 BMY

Ògo Òfin Ọlọ́run

1 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́sẹ̀,ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa,

2 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin Rẹ̀ mọ́tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

3 Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;wọ́n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀.

4 Ìwọ ti la ìlànà Rẹ̀ sílẹ̀kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

5 Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣinláti máa pa òfin Rẹ̀ mọ́!

6 Nígbà náà, ojú kò ní tì mínígbà tí mo bá ń kíyèsí àṣẹ Rẹ̀ gbogbo.

7 Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣinbí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo Rẹ̀.

8 Èmi yóò gbọ́ràn sí asẹ Rẹ̀:Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátapáta.

9 Báwo ni àwọn èwe ènìyàn yóò ti ṣe pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́?Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mimá ṣe jẹ́ kí èmi yàpa kúrò nínú àṣẹ̀ Rẹ.

11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ ní ọkàn mikí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ

12 Ìyìn ni fún Olúwa;kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún sírògbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu Rẹ.

14 Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹbí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá.

15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹèmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ

16 Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ;èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ.

Ohun Ìyanu Tí Ó Wà Nínú Òfin Rẹ̀

17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè;èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

18 La ojú mi kí èmi lè ríran ríohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ.

19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;Má ṣe pa àṣẹ Rẹ mọ́ fún mi.

20 Ọkàn mi pòrúúru pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin Rẹ nígbà gbogbo.

21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn-úntí ó sìnà kúrò nínú àṣẹ Rẹ.

22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,nítorí èmi pa òfin Rẹ mọ́.

23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọ̀pọ̀, wọ́nń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ Rẹ.

24 Òfin Rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbadámọ̀ràn mi.

Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

25 Èmi tẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ sínú erùpẹ̀;pa ayé mi mọ́ sí ipa ọ̀rọ̀ Rẹ.

26 Èmi tún ọ̀nà mi síròṣ ìwọ sì dá mí lóhùn;kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

27 Jẹ́ kí ń mọ ẹ̀kọ́ ìlànà Rẹ̀:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu Rẹ.

28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tànfún mi ní oore ọ̀fẹ́ nípa òfin Rẹ.

30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin Rẹ.

31 Èmi yára di òfin Rẹ mú. Olúwamá ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ,nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

Ìlérí Ọlọ́run Fún Aláforítì

33 kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ Rẹ;nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́èmi yóò sì máa kíyèsíi pẹ̀lú ọkàn mi.

35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ Rẹ hàn mí,nítorí nínú Rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

36 Yí ọkàn mi padà sí òfin Rẹ̀kí ó má ṣe sí ojú kòkòrò mọ́.

37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:pa ayé mí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

38 Mú ìlérí Rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí òfin Rẹ dára.

39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rùni torí tí idájọ́ Rẹ dára.

40 Kíyèsíi ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ Rẹ!Pa ayé mí mọ́ nínú òdodo Rẹ.

Ìgbàlà lati inú òfin Ọlọ́run

41 Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,ìgbàlà Rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ;

42 Nígbà náà ni èmi yóò dáẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ.

43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu minítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ Rẹ

44 Èmi yóò máa gbọ́ràn sí òfin Rẹ nígbà gbogboláé àti láéláé.

45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jáde.

46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin Rẹ níwájú àwọn ọbaojú kì yóò sì tì mí,

47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ Rẹnítórí èmi ni ìfẹ́ wọn.

48 Èmi gbé ọwọ̀ mi sókè nítorí àṣẹ Rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,èmi sì ń ṣe àsàrò òfin Rẹ̀.

Òfin Ọlọ́run Ní Ìrètí

49 Rántí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.

50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:ìpinu Rẹ pa ayé mi mọ́.

51 Àwọn agbéraga fi mi ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin Rẹ.

52 Èmi rántí àwọn òfin Rẹ ìgbàanì, Olúwa,èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.

53 Ìbínú dìmí mú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburútí wọ́n ti kọ òfin Rẹ sílẹ̀.

54 Òfin Rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin miníbikíbi tí èmi ń gbé.

55 Ní òru èmi rántí orúkọ Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́

56 nitori ti mogba ẹ̀kọ́ Rẹ gbọ́.

Ọlọ́run Ni Ìpín Wa

57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

58 Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

59 Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mièmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ.

60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́raláti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ.

61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

62 Ní àárin ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọnítorí òfin òdodo Rẹ̀.

63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

64 Ayé kún fún ìfẹ́ Rẹ OlúwaKọ́ mi ní òfin Rẹ.

Ìpọ́njú Mu Ni Mọ Òfin Ọlọ́run

65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹgẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa.

66 Kọ́ mi ni ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ Rẹ.

67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti sìnà,ṣùgbọ́n ni ìsinsinyí èmi gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;kọ́ mi ní ìlànà Rẹ.

69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti Rẹ̀ mí pẹ̀lú èkéèmi pa ẹ̀kọ́ Rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin Rẹ.

71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójúnítorí kí èmi lè kọ́ òfin Rẹ.

72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu Rẹ ju iyebíye sí mi lọó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ

Ẹlẹgbẹ́ Mi Ni Àwọn Tó Mo Òfin Olúwa

73 Ọwọ́ Rẹ ní ó dá mi tí ó sì mọ mí;fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ Rẹ.

74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ máa yọ̀nígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

75 Èmi mọ̀, Olúwa, nítorí òfin Rẹ òdodo ni,àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

76 Kí ìfẹ́ Rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ sí ìránṣẹ́ Rẹ.

77 Jẹ́ kí àánú Rẹ kí ó tọ̀ò mí wá kí èmi kí ó lè yè,nítorí òfin Rẹ̀ jẹ́ ìdùnnú mi.

78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraganítorí wọn pamí lára láìnídìíṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ̀.

79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ yí padà sí mí,àwọn tí ó ní òye òfin Rẹ.

80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin Rẹ,kí ojú kí ó má ṣe tì mí.

Wíwá Àlàáfíà

81 Ọkàn mi ń fojú sọ́nà nítorí ìgbàlà Rẹ,ṣùgbọ́n èmi tí mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wí wo ìpinu Rẹ;èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”

83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí àmọ́ wáìnì nínú èéfín,èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

84 Báwo ni ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọntí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?

85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,tí ó lòdì sí òfin Rẹ.

86 Gbogbo àsẹ Rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:rànmílọ́wọ́, nítorí ènìyànń ṣe inúnibíni sí mi láì nídìí.

87 Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,ṣùgbọ́n èmi kò kọ̀ ẹ̀kọ́ Rẹ.

88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ,èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu Rẹ̀ gbọ́.

Ọ̀rọ̀ Olúwa Dúró Títí Láí

89 Ọ̀rọ̀ Rẹ, Olúwa, títí láé ni;ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run

90 Òtítọ́ Rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.

91 Òfin Rẹ dúró di ònínítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.

92 Bí òfin Rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.

93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ láé,nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́

94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹèmi ti wá ẹ̀kọ́ Rẹ.

95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsí ẹ̀rí Rẹ.

96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;ṣùgbọ́n àṣẹ Rẹ aláìlópin ni.

Òfin Olúwa Ni Ìfẹ́ Pípé

97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin Rẹ tó!Èmi ń ṣe àṣàrò nínú Rẹ̀ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.

98 Àṣẹ Rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀ta mi lọ,nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.

99 Èmi ní iyè ińu ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin Rẹ.

100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,nítorí mo gba ẹ̀kọ́ Rẹ.

101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibinítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ Rẹ.

102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ìwọ fún rarẹ̀ ni ó kọ́ mi.

103 Báwo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!

104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ Rẹ;nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

Òfin Olúwa Ni Fítílà Mi

105 Ọ̀rọ̀ Rẹ ni ó ṣe fítílà sí ẹṣẹ̀ miàti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi

106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọnwí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo Rẹ.

107 A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Rẹ

108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,kí o sì kọ́ mi ní òfin Rẹ̀.

109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ minígbà gbogbo,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.

110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,ṣùgbọ́n èmi kò sìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Rẹ.

111 Òfin Rẹ ni ogún mi láéláé;àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.

112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin Rẹ mọ́láé dé òpin.

Òfin Olúwa Ni Ààbò Mi

113 Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.

114 Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!

116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ.

118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọyọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.

120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ

Olorin Pa Òfin Olúwa Mọ

121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mi sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.

122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ Rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

123 Ojú mi kùnà, fún wí wo ìgbàlà Rẹ,fún wíwo ìpinu òdodo Rẹ.

124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹkí o sì kọ́ mi ní àṣẹ Rẹ.

125 Èmi ni ìránṣẹ́ Rẹ; ẹ fún mi ní òyekí èmi lè ní òye òfin Rẹ

126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;nítorí òfin Rẹ ti fọ́.

127 Nítorí èmi fẹ́ràn àsẹ Rẹju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

128 Nítorí èmi kíyèsí gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ Rẹ̀,èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

Àdúrà Láti Le Pa Òfin Olúwa Mọ

129 Òfin Rẹ̀ ìyanu ni:nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.

130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;ó fi òye fún àwọn òpè.

131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,nítorí èmi fojú sọ́nà sí ṣsẹ Rẹ.

132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọntí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ.

133 Fi ìsísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ,má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ.

135 Jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ Rẹ lárakí ó sì kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.

136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,nítorí wọn kò gba òfin Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.

137 Olódodo ni ìwọ Olúwaìdájọ́ rẹ sì dúró sinsin

138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.

139 Ìtara mi ti pami run,nítorí àwọn ọ̀ta mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ Rẹ dá.

140 Wọ́n ti dán ìpinnu Rẹ wò pátapátaìránṣẹ́ Rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gànèmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ Rẹ.

142 Òdodo Rẹ wà títí láéòtítọ́ ni òfin Rẹ̀.

143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,ṣùgbọ́n àsẹ Rẹ ni inú dídùn mi,

144 Òfin Rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;fún mi ní òyé kí èmi lè yè.

Kíkígbe Fún Ìgbàlà

145 èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:dámi lóhùn Olúwa,èmi yóò sì gbọ́ràn sí àsẹ Rẹ.

146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà míèmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́.

147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìràn lọ́wọ́;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.

148 Ojú mi ṣááju ìsọ́ òru,nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ r.

149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ:pa ayé mí mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòòsí,ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin Rẹ.

151 Ṣíbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,àti gbogbo àsẹ Rẹ jẹ́ òtítọ́.

152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin Rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

Pípa Òfin Mọ́ Ní Ìpọ́njú

153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin Rẹ.

154 Gba ẹjọ́ mi rò kí ó sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ Rẹ.

156 Ìyọ́nú Rẹ̀ tóbi, Olúwa;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Rẹ.

157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀ta tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tíì yí padà kúrò nínú òfin Rẹ.

158 Èmi wọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́.

159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Rẹ;pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ.

160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ Rẹ;gbogbo òfin òdodo Rẹ láéláé ni.

161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ Rẹ.

162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu Rẹbí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.

163 Èmi kórìíra mo sì gba èké ṣíṣeṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin Rẹ.

164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́nítorí òfin òdodo Rẹ.

165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin Rẹ,kò sì si ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ Rẹ.

167 Èmi gba òfin Rẹ gbọ́,nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀ púpọ̀

168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ Rẹ àti òfin Rẹ,nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.

169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú Rẹ, Olúwa;fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ.

170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú Rẹ;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.

171 Ètè mi yóò sọ ìyin jáde,nítorí ìwọ kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ.

172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ Rẹ,nítorí gbogbo àṣẹ Rẹ jẹ́ òdodo.

173 Jẹ́ kí ọwọ́ Rẹ ṣetan láti rànmílọ́wọ́,nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ Rẹ.

174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà Rẹ, Olúwa,àti òfin Rẹ jẹ́ dídùn inú mi.

175 Jẹ́ kí èmi wà láàyè ki èmi lè yìn ọ́,kí o sì jẹ́ kí òfin Rẹ mú mi dúró.

176 Èmí ti sìnà bí àgùntàn tí ósọnùú wá ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ Rẹ.