Sáàmù 103 BMY

Ọpẹ́ Fún Dídara Ọlọ́run

1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́.

2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore Rẹ̀

3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ jìn ọ́ tíó sì wo gbogbo àrùn Rẹ̀ sàn,

4 Ẹni tí o ra ẹ̀mí Rẹ padà kúrò nínú kòtò ikúẹni tí o fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

5 Ẹni tí o fi ohun dídara tẹ́ ọ lọ́rùnkí ìgbà èwe Rẹ̀ le di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fúngbogbo àwọn tí a nilára.

7 Ó fi ọ̀nà Rẹ̀ hàn fún Mósè, iṣẹ́ Rẹ̀ fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

8 Olúwa ni aláàánú àti olóore,ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbobẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú Rẹ mọ́ láéláé;

10 Òun kì í ṣe sí wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wabẹ́ẹ̀ ni kì í san-án fún wa gẹ́gẹ́bí àìṣedédé wa.

11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

12 Bí ìlà òòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ òòrunbẹ́ẹ̀ ní ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí bàbá ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ Rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀;

14 Nítorí tí ó mọ dídá wa,ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ Rẹ̀ dà bí koríko,ó gbilẹ̀ bí ìtànnà ewéko ìgbẹ́;

16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí Rẹ̀,kò sì rántí ibùjókòó Rẹ̀ mọ́.

17 Ṣùgbọ́n láti ayé rayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti òdodo Rẹ̀ wà láti ọmọ dé ọmọ

18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́àti àwọn tí ó rántí òfin Rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ Rẹ̀ nínú ọ̀run,ìjọba Rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20 Yin Olúwa, ẹ̀yin ańgẹ́lì Rẹ̀ tí ó ní ipá,tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́

21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run Rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ níibi gbogbo ìjọba Rẹ̀.Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.