Sáàmù 66 BMY

Orin Ọpẹ́ Fún Dídara Ọlọ́run Sí Ísírẹ́lì

1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ayé!

2 Ẹ kọrin ọ̀lá orúkọ Rẹ̀;Ẹ fún un ní ìyìn, ògo,

3 Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀!Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀táRẹ yóò fi sìn ọ́.

4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ.” Sela

5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!

6 O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá,níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.

7 O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀,ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdèkí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela

8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohun ìyìn Rẹ̀;

9 O ti dá ààbò bo ẹ̀mí wakò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí o yẹ̀

10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, Dan wa wò;ìwọ dán wa bí a tí ń Dan fàdákà wo

11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀no sì di ẹ̀rù lé ẹ̀yìn wa

12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gun wá ní oríàwa la iná àti omi kọjáṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

13 Èmi ó wá sí tẹ́ḿpìlì Rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísunkí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ

14 Ẹ̀jẹ́ ti ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọnígbà tí mo wà nínú ìsòro.

15 Èmi o sun ẹbọ ọlọ́ràá sí ọàti ẹbọ ọ̀rá àgbò;èmi o rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela

16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa;ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.

17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:Ìyìn Rẹ̀ wà ní ẹnu mi.

18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;

19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́o ti gbọ́ ohun mi nínú àdúrà.

20 Ìyìn ni fún Ọlọ́runẹni tí kò kọ àdúrà mitàbí mú ìfẹ́ Rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!