1 Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá ni kíÍsírẹ́lì kí ó wí nísinsinyí
2 Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá;ṣíbẹ̀ wọn kò tíì borí mi.
3 Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:wọ́n sì là aporo wọn gígùn.
4 Olódodo ní Olúwa:ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.
5 Kí gbogbo àwọn tí ó korìíra Síónì kí ó dààmú,kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6 Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀tí ó gbẹ dànù kí o tó dàgbà sókè:
7 Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ Rẹ̀:bẹ́ẹ̀ ní ẹni tí ń di ìtì, kó kún apá Rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kó wí pé,ìbùkún Olúwa kí o pẹ̀lú yín:àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.