1 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjòkòó mi àti ìdìde mi,ìwọ mọ̀ ìrò mi ní ọ̀nà jnijin réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi kán àti idùbúlẹ̀ mi,gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.
4 Nítorí ti kò si ọ̀rọ kan ní ahọ́n mi,kíyèsíi, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátapáta.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,ìwọ sì fi ọwọ́ Rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù;ó ga, èmi kò le mọ̀.
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ní ọwọ́ ẹ̀mí Rẹ?Tàbí níbo ní èmi yóò sáré kúrò níwájú Rẹ?
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀.
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin òkun;
10 Àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ Rẹ̀ yóò fà míọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì dì mí mú.
11 Bí mo bá wí pé, ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọdọ̀ Rẹ;ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjìbákan náà ní fún ọ.
13 Nítorí ìwọ ní ó dá ọkàn mi;ìwọ ní ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àtitìyanu tìyanu ní a dá mi;ìyanu ní isẹ́ Rẹ; èyí nì níọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọdọ̀ Rẹ,nígbà tí á dá mi ní ìkọ̀kọ̀,tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà níìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
16 Ojú Rẹ̀ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé:àti nínú ìwé Rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí,ní ojojumọ́ ni a ń dá wọn,nígbà tí ọ̀kan wọn kò tí i sí.
17 Ọlọ́run, ìrò inú Rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ibá kà wọ́n, wọ́n jù iyanrin lọ ní iye:nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ Rẹ̀ ṣíbẹ̀
19 Ọlọ́run ibá jẹ pa àwọn ènìyàn búburú ní tòótọ́;nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,àwọn ọ̀tá Rẹ ń pe orúkọ Rẹ ní aṣán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò korìíra àwọn tó korìíra Rẹ?Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi korìíra wọn ní àkótán;èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádíì mi, kí ó sì mọ ọkàn mí;dán mi wò, kí ó sì mọ ìrò inú mi
24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburúkan bá wà nínú mi kí ó sìfi ẹṣẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.