1 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀ta mi ṣe pọ̀ tó!Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé“Ọlọ́run kò ní gbà á là.”
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni àṣà yí mi ká, Olúwa;iwọ fi ogo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá.
5 Èmi dúbùú lẹ̀, mo sì sùn;mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàntí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7 Dìde, Olúwa!Gbà mí, Ọlọ́run mi!Lu gbogbo àwọn ọ̀ta mi ní àgbọ̀n;kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.Kí ìbùkún Rẹ̀ wà lóri àwọn ènìyàn Rẹ̀. Sela