Sáàmù 39 BMY

Àdúrà Fún Ọgbọ́n Àti Ìdáríjìn

1 Mo wí pé,èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mikí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnuníwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburúbá ń bẹ ní iwájú mi.

2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ síi.

3 Àyà mi gbóná ní inú mi,nígbà tí mo ń ṣàṣàrò,ina ràn;nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀.

4 Olúwa,jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti ríkí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

5 Ìwọ ti ṣe ayé mibí ìbú àtẹ́lẹwọ́,ọjọ́ orí mi sì dàbí asánní iwájú Rẹ:Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínúìjókòó rere Rẹ̀ jásí asán pátapáta. Sela

6 Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

7 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, Olúwa,kín ni mo ń dúró dè?Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Rẹ.

8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gànàwọn ènìyàn búburú.

9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;èmi kò sì ya ẹnu mi,nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

10 Mú ìnà Rẹ̀ kúrò ní ara mi;èmí ṣègbé tán nípa ìlù ọwọ́ Rẹ.

11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ a mú ẹwà Rẹ parunbí kòkòrò aṣọ;nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,kí o sì fetí sí igbe mi;kí o má ṣe di etí Rẹ sí ẹkún minítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ Rẹàti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,kí èmi tó lọ kúrò níhín-ín yìí,àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”