Sáàmù 136 BMY

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn Olúwa,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

6 Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

7 Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé

8 Òòrùn láti jọba ọ̀sán;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

9 Òsùpá àti ìràwọ̀ láti jọba òru;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

10 Fún ẹni tí ó kọlu Éjíbítì lára àwọn àkọ́bí wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

11 Ó sì mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàrin wọn;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

13 Fún ẹni tí ó pín òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

14 Ó sì mú Ísírẹ́lì kọjá láàrin Rẹ̀nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

15 Ṣùgbọ́n ó bi Fáráò àti ogun Rẹ̀ ṣubú nínú òkun pupa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn Rẹ̀ la ihà jánítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

17 Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

19 Síónì, ọba àwọn ará Ámórìnítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

20 Àti Ógù, ọba Báṣánì;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

22 Ìní fún Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ Rẹ̀,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbonítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.