1 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;Èmi yóò yin orúkọ Rẹ̀ láé àti láéláé
2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Rẹ láé àti láéláé.
3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi Rẹ̀.
4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ Rẹ dé ìran mìíràn;wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára Rẹ
5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọlá ńlá Rẹ tí ó lógo,èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu Rẹ.
6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára Rẹ tí ó ní ẹ̀rùèmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá Rẹ̀.
7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ìwà rere Rẹ àti orin ayọ̀ òdodo Rẹ.
8 Olore òfẹ́ ni Olúwa àti aláàánúó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀,
9 Olúwa dára sí ẹni gbogbo;ó ní àánú lóri ohungbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá niyóò máa yìn ọ́ Olúwa;àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí Rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba Rẹwọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára Rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ isẹ́ agbára rẹ̀àti ola ńlá ìjọba Rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba Rẹ ìjọba ayérayé ni,àti ìjọba Rẹ wà ní gbogbo ìran-díran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú róó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ sí ọwọ́ Rẹìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà Rẹ̀àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ṣẹ;ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ síṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹnibúburú ní yóò parun.
21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ Rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.