Sáàmù 59 BMY

Àdúrà Fún Ìtúsílẹ̀ Lọ́wọ́ Ìdè Ọ̀tá

1 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.

2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburúkí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

3 Wòó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí miKìí se nítorí ìrékọja mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.

4 Èmí kò ṣe àìṣedédé kan, ṣíbẹ̀ wọ́n sáré,wọ́n ṣetán láti kọlù mi. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi,kí o sì wo àìlera mi.

5 Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,dìde fún ara Rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀ èdè wí;Má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela

6 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.

7 Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,wọn sì wí pé, “Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

8 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rin-ínÌwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.

9 Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

10 Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi.

11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé.Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri,kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,ni ọ̀rọ̀ ètè wọn,kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,

13 Pa wọn run nínú ìbínú,run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́.Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayépé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù. Sela

14 Wọ́n padà ní àsálẹ́,wọn ń gbó bí àwọn ajáwọ́n ń rìn ìlú náà káàkiri.

15 Wọ́n ń rín kiri fún oúnjẹwọn sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.

16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára Rẹ,ń ó kọrin ìfẹ́ Rẹ ní òwúrọ̀;nítorí ìwọ ni ààbò mi,ibi ìsádì mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.