Sáàmù 34 BMY

1 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;ìyìn Rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè.

4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

5 Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;ojú kò sì tì wọ́n

6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn Rẹ̀;ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀.

7 Ángẹ́lì Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ káó sì gbà wọ́n.

8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀.

9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

12 Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

13 Pa ahọ́n Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibiàti ètè Rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;wá àlàáfíà, kí o sì lépa Rẹ̀.

15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn.

16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17 Nígbà tí Olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

18 Olúwa sún mọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;ó sì gba irú àwọn tí i ṣe oníròra ọkàn là.

19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo Rẹ̀.

20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.

22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ padà;kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀le tí yóò jẹ̀bi.