Sáàmù 148 BMY

1 Ẹ fi ìyìn fún OlúwaẸ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wáẸ fi ìyìn fún un níbi gíga

2 Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ángẹ́lì Rẹ̀Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun Rẹ̀

3 Ẹ fi ìyìn fún un,oòrùn àti òṣùpáẸ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

4 Ẹ fi ìyìn fún un,ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run gígaàti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run

5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláéó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wáẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbiàti ẹ̀yin ibú òkun

8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyínìdí omi àti àwọn ìkùùku,ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;

9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kékèké,igi eléso àti gbogbo igi kédárì,

10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìngbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:

11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn áye gbogboàwọn ọmọ aládé àti gbogbo àwọn onídájọ́ ayé,

12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinàwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí orúkọ Rẹ̀ nìkan ni ó ní ọláògo Rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn Rẹ̀,ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.