1 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi péẸ jẹ́ kí a lọ sílé Olúwa.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè Rẹ,ìwọ Jérúsálẹ́mù.
3 Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlútí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,àwọn ẹ̀yà Olúwa,ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, látimáa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù;àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀,àti ire nínú ààfin Rẹ̀.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mièmi yóò wí nísinsìyí pé,kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀;
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,èmi yóò máa wá ire Rẹ̀.