Sáàmù 132 BMY

1 Olúwa, rántí Dáfídìnínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀:

2 Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,tí ó sì ṣe ìlèrí fún Alágbára Jákọ́bù pé.

3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gùn orí àkéte mi:

4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

5 Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,ibùjókòó fún Alágbára Jákọ́bù.

6 Kíyèsí i, àwa gbúroo Rẹ̀ ni Éfúrátà:àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ Rẹ̀:àwa ó máa sìn níbi àpótí-ìtìsẹ̀ Rẹ̀

8 Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi Rẹ:ìwọ, àti àpótí agbára Rẹ.

9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà Rẹ:kí àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

10 Nítorí tí Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀Má ṣe yí ojú ẹni-òróró Rẹ padà.

11 Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dáfídì:Òun kí yóò yípadà kúrò nínú Rẹ̀,nínú irú ọmọ inú Rẹ ní èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ Rẹ.

12 Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókoo lórí ìtẹ́ Rẹ láéláé.

13 Nítorí tí Olúwa ti yan Síónì:ó ti fẹ́ẹ fún ibùjókòó Rẹ̀.

14 Èyí ní ibi ìsinmi mí láéláé:níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:nítorí tí mo fẹ́ ẹ.

15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ Rẹ̀ púpọ̀ púpọ̀:èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà Rẹ̀ lọ́rùn.

16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlúfáà Rẹ̀:àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwọ Dáfídì yọ̀,èmi ti ṣe ìlànà fítílà kan fún ẹni òróró mi.

18 Àwọn ọ̀tá Rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:ṣùgbọ́n lára Òun tìkararẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.