Sáàmù 33 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìyàanjú Láti Máa Yin Olúwa

1 Ẹyọ̀ nínú Olúwa,ẹ̀yin olódodoìyín si yẹ fún ẹnidídúró ṣinṣin.

2 Ẹyin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin síi,pẹ̀lú ariwo ńlá.

4 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ni à ń ṣenínú òtítọ́.

5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

6 Nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu Rẹ̀.

7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;ó sì fi ibú sí ilé ìṣúra gbogbo.

8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayékí ó wà nínú ìbẹ̀rù Rẹ̀.

9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹó sì dúró ṣinṣin.

10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀ èdè wá sí asán;ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákìí.

11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.

13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14 Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsí ìṣe wọn.

16 A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.

17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun;bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀.

18 Wòó ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin,

19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikúàti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn.

20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti aṣà wa.

21 Ọkàn wa yọ̀ nínú Rẹ̀,nítorí pé, àwa gba orúkọ mímọ́ Rẹ̀ gbọ́

22 Kí àánú Rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú Rẹ.