Sáàmù 84 BMY

Ayọ̀ Ìjọ́sin Ni Tẹ́ḿpìlì

1 Ibùgbé Rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa Olódùmarè!

2 Ọkàn mí ń fà nítòótọ́ó tilẹ̀ pòùngbẹ fún àgbàlá Olúwaàyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọ́run alààyè.

3 Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé,ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r,níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí:ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

4 Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé Rẹ;wọn o máa yìn ọ́ títí láé.

5 Ìbùkún ní fún àwọn tí agbára wọn wà nínú Rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

6 Àwọn tí ń la àfonífojì omije lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;

7 Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Síónì.

8 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jákọ́bù.

9 Wo àsà wa, Ọlọ́run;fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òroro Rẹ.

10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin Rẹju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run miju láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrun àti àṣà; Olúwa fúnni ní ojúrere àti ọlá;kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn dádúrófún àwọn tí o rin ní aílábùkù.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.