Sáàmù 57 BMY

Àdúrà Fún Ìdáǹdè Nínú Ìpọ́njú

1 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,nítorí nínú Rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.Èmi o fi ààbò mí síbi ìyẹ́ apá Rẹtítí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run gíga jùlọ,sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́ fún mi.

3 Òun yóò ránsẹ́ láti ọ̀run wá,yóò sì gbà mí bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mì mìtilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.Ọlọ́run yóò rán àánú Rẹ̀ àti òdodo Rẹ̀ jáde.

4 Mo wà ní àárin àwọn kìnnìún;mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburúàwọn ènìyàn tí ẹ̀yin wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfàẹni tí ahọ́n Rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọkí ògo Rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

6 Wọn ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjúwọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:ṣùgbọ́n wọn ti jìn ṣíbẹ̀ fún ara wọn.

7 Ọkàn mi tí múra Ọlọ́run;ọkàn mí ti múra, èmi ó kọrin èmi ó si máa kọrin ìyìn.

8 Jí, ìwọ ọkàn mi!Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!Èmi tìkárami, yóò si jí ní kùtùkùtù.

9 Èmi ó máa yín ọ, Olúwa, láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;èmi ó máa kọrin sí ọ láàrin àwọn ènìyàn.

10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ Rẹ, tí ó dé ọ̀run;òtítọ́ Rẹ tàn dé àwọ̀sánmọ̀.

11 Gbígbéga ni ọ, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;kí ògo Rẹ̀ kí ó ju gbogbo ayé lọ.