Sáàmù 42 BMY

ÌWÉ KEJÌ

1 Bí àgbọ̀nrín tí ń mí hẹlẹ sí ìpa odò omi,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi n mì hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run

2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

3 Oúnjẹ mi ní omijé miní ọ̀sán àti ní òru,nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́,“Ọlọ́run Rẹ̀ dà?”

4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́runpẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

5 Èéṣe tí o fi n rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?Ìwọ ṣe ìrètí ni ti Ọlọ́run,nítorí èmi yóò sáà máa yìn ín.

6 Olùgbàlà mi àtiỌlọ́run mi,ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:nítorí náà, èmi ó rántí Rẹláti ilẹ̀ Jọ́dánì wá,láti Hámónì láti òkè Mísárì.

7 Ibú omi ń pe ibú ominípa híhó omi ṣíṣàn Rẹ̀gbogbo rírú omi àti bíbì omi Rẹ̀bò mí mọ́lẹ̀.

8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ Rẹ̀,àti ni àṣálẹ́ ni orin Rẹ̀ wà pẹ̀lú miàdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpátà mi,“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,nítorí ìnilára ọ̀ta?”

10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tíàwọn ọ̀ta mi ń gàn mí,Bí wọn ti ń béèrè ni gbogbo ọjọ́.“Níbo ni Ọlọ́run Rẹ wà?”

11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run,nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun niOlùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.