Sáàmù 147 BMY

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa nítorí ohun rereláti máa kọrin ìyìnsí Ọlọ́run wa,ó yẹ láti kọrin ìyìn síi.

2 Olúwa kọ́ Jérúsálẹ́mù;O ko àwọn Ísírẹ́lì tí a lé sọnù jọ.

3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bajẹ́ sànó sì di ọgbẹ́ wọn.

4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ó sì pe ọ̀kọ̀ọkan wọn ní orúkọ

5 Títóbi ní Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbáraòye Rẹ̀ kò sì ní òpin.

6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ó Rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwafi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

8 Ó fi ìkuukù bo àwọ sánmọ̀ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayéó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

9 Ó pèṣè oúnjẹ fún àwọn ẹrankoàti fún awọn ọmọ àdàbà ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹsinbẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

11 Olúwa ní ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú Rẹ̀.

12 Yin Olúwa, ìwọ Jérúsálẹ́mùyin Ọlọ́run Rẹ̀, ìwọ Síónì.

13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ìbodè Rẹ̀ lágbára;Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú Rẹ

14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè Rẹ̀òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.

15 Òun sì rán àṣẹ Rẹ̀ sí ayéọ̀rọ̀ Rẹ̀ sáré tete.

16 Ó fi sino fún ni bi irun àgùntànó sì fọ́n ìrì idídì ká bí eérú

17 Ó rọ òjò yìnyín Rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ta ni ó lè dúró níwájú òtútù Rẹ̀

18 Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ó mú kí afẹ́fẹ́ Rẹ̀ fẹ́ó sì mú odò Rẹ̀ sàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ di mímọ̀ fún Jákọ́bùàwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀ fún Ísírẹ́lì

20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀ èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ Rẹ̀wọn ko mọ òfin Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.