1 Èmi yóò yìn ọ́ tinú tinú mi gbogbo;níwájú àwọn òrìṣà ní èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀èmi ó sì máa yin orúkọ Rẹnítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ àti òtítọ́ Rẹ;nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ Rẹ ga ju orúkọ Rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo képè ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ
5 Nítòótọ́, wọn o máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;nítorí pé ńlá ní ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, ṣíbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;ṣùgbọ́n agbéraga ní ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di àyè;ìwọ ó nà ọwọ́ Rẹ̀ si àwọn ọ̀tá mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; Olúwa, àánú Rẹ̀ dúró láéláé;Má ṣe kọ isẹ́ ọwọ́ ara Rẹ̀ sílẹ̀.