Sáàmù 5 BMY

Àdúrà Òwúrọ

1 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,kíyèsí àròyé mi.

2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,ọba mi àti Ọlọ́run mi,nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;ní òwúrọ̀ èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú Rẹ̀èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

5 Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú Rẹ̀;ìwọ kóríra gbogbo àwọn aṣebi.

6 Ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run;apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyànni Olúwa yóò kórìíra.

7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú Rẹ̀,èmi yóò wá sínú ilé Rẹ̀;ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríbasí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀.

8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo Rẹ,nítorí àwọn ọ̀ta mi,mú ọ̀nà Rẹ tọ́ níwájú mi.

9 Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;ọkàn wọn kún fún ìparun.ọ̀nà ọ̀fun wọn ni iṣà òkú tí ó sí sílẹ̀;pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!Jẹ́ kí rìkísí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.Tan ààbò Rẹ sórí wọn,àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ yóò máa yọ̀ nínú Rẹ.

12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;ìwọ fi ojú rere Rẹ yí wọn ká bí àṣà.