Sáàmù 68 BMY

Orin Ìyìn Òun Ọpẹ́

1 Kí Ọlọ́run kí o dìde, kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó fọ́nká;kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó sá níwájú Rẹ̀.

2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,kí ó fẹ́ wọn lọ;bí ìdà tí i yọ́ níwájú iná,kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.

3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùnkí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,ẹ kọrin ìyìn síi,ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń ré kọjá ní ihà.JAH ni orúkọ Rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Rẹ̀.

5 Baba àwọn aláìní baba àti Onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ni ibùgbéRẹ̀ mímọ́

6 Ọlọ́run gbé ẹni òfokálẹ̀ nínú ìdílé,ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orinṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ọlọ́run,tí ń kọjá lọ láàrin ihà, Sela

8 Ilẹ̀ mi títí,àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,níwájú Ọlọ́run,ẹni Sínáì,níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;ìwọ tu ilé inú Rẹ̀ lára nígbà tí ó Rẹ̀ ẹ́ tan.

10 Àwọn ènìyàn Rẹ tẹ̀dó ṣíbẹ̀nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní Rẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí o ń ròyìn Rẹ.

12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;Obìnrín tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.

13 Nígbà tí ẹ̀yin sùn láàrin àwọn àgọ́ iná,nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí apá àdàbà ti a bò ní sílífa.”

14 Nígbà ti Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,ó dàbí òjò dídi ní Salímónì.

15 Òkè Básánì jẹ́ òkè Ọlọ́run;òkè tí ó ní orí púpọ̀ ní òkè Básánì.

16 Kí ló dé ti ẹ̀yin fi ń lára,ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jọbaníbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?

17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́runẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrin wọn ní Sínáì ni ibi mímọ́ Rẹ̀.

18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gígaìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbékùn lọ;ìwọ ti gbà ẹ̀bùn fún ènìyàn:nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19 Olùbùkún ni Ọlọ́run,sí Ọlọ́run Olùgbàlà wa,ẹni tí ó ń fi ojojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela

20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlààti sí Olúwa Ọlọ́run ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá Rẹ̀,àti agbárí onirun àwọn tó ń tẹ̀ṣíwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn

22 Olúwa wí pé, “Èmi o mú wọn wá láti Báṣánì;èmi ó mú wọn wá láti ibú omi òkun,

23 Kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá Rẹ̀,àti ahọ́n àwọn ajá Rẹ̀ ní ìpín ti wọn lára àwọn ọ̀tá Rẹ.”

24 Wọn ti rì ìrìn Rẹ, Ọlọ́run,irin Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

25 Àwọn akọrin ní íwájú,tí wọn ń lu tanborí

26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Ísírẹ́lì wá.

27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Bẹ́ńjámínì wà, tí o ń darí wọn,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Júdà,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Sébúlúnì àti tí Náfútàlì.

28 Pàsẹ agbára Rẹ, Ọlọ́run;fi agbára Rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀.

29 Nítorí tẹ́ḿpìlì Rẹ ni Jérúsálẹ́mùàwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.

30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,tí ń gbé láàrin ìkoọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúùpẹ̀lú àwọn ọmọ màlúùtítí olúkúlùkù yóò fi forí balẹ̀ pẹ̀lú ìwọn fàdákà:tú àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe inú dídùn si ogun ká

31 Àwọn ọmọ aládé yóò wá láti Éjíbítì;Jẹ́ kí Etiópíà na ọwọ́ Rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela

33 Sí ẹni tí ń gún ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,tó ń fọhùn Rẹ̀, ohùn ńlá.

34 Kéde agbára Ọlọ́run,ọlá ńlá Rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lìtí agbára Rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ Rẹ;Ọlọ́run Ísírẹ́lìfi agbára àti òkun fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.Olùbùkún ní Ọlọ́run!