Sáàmù 88 BMY

Kíké Pé Ọlọ́run Fún Ìrànlọ́wọ́

1 Olúwa, Ọlọ́run tí o gba mí là,ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.

2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí o wá sí iwájú Rẹ;dẹ etí Rẹ̀ sí igbe mi.

3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njúọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.

4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀èmi dà bí ọkùnrin tí kò ni agbára.

5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkúbí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jínjìn,ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.

7 Ìbínú Rẹ ṣubú lé mi gidigidi;ìwọ ti fi àwọn ìjì Rẹ̀ borí mi.

8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mí kúrò lọ́wọ́ miìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.A há mi mọ́, èmi kò sì lé è jáde;

9 Ojú mi káànú nítorí ìpọ́njú.Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;mo na ọwọ́ mí jáde sí ọ.

10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu Rẹ hàn fún òkú?Àwọn òkú yóò ha dìde láti yín ọ́ bí?

11 A ó ha fi iṣeun ifẹ́ Rẹ hàn ni ibojì bí:Tàbí òtítọ́ Rẹ ni ipò iparun?

12 A ha le mọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ ní òkùnkùn bíàti òdodo Rẹ ní ìlà ìgbàgbé?

13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;ní òwúrọ̀ ní àdúrà mí wá sọ́dọ̀ Rẹ.

14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mítí ìwọ fi ojú Rẹ pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,èmi múra àti kú;nígbà ti ẹ̀ru Rẹ ba ń bà mí,èmi di gbére-gbère

16 Ìbínú Rẹ ti kọjá lára mi;ìbẹ̀rù Rẹ ti ge mi kúrò

17 Ní gbogbo ọjọ́ ní wọn yí mi ká bí ìkún omi;wọ́n mù mí pátápátá.

18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.