1 Ìrékọjá sọ̀rọ̀ sí ènìyàn búburújinlẹ̀ nínú ọkàn wọn;Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò síníwájú ojú wọn
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọntítí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn;wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkànígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára:wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ,ìwọ Olúwa,ó ga dé ọ̀run,òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà.
6 Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá;ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó!Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn lesá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ.
8 Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùngidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn munínú odò inú-dídùn Rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú ù Rẹ ni orísun ìyè wà:nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ Rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́àti ìgbàlà Rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ agbéragakí ó wá sí orí mi,kí ọwọ́ àwọn ènìyànbúburú sí mi ni ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀gbé subú sí:a Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,wọn kì yóò le è dìde!