Sáàmù 83 BMY

Àdúrà Ìdájọ́ Lórí Ọ̀ta Ísírẹ́lì

1 Ọlọ́run, Má ṣe dákẹ́;Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ ẹ́.

2 Wo bí àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,bi àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.

3 Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ;wọn gbìmọ̀ lòdì sí àwọn tí ó fẹ.

4 Wọn wí pé, “wá,” ẹ jẹ́ kí a pa wọn run bí orílẹ̀ èdè,kí orúkọ Ísírẹ́lì ma bá a sí ní ìrántí mọ́.

5 Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ

6 Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ara Íṣímaélì,tí Móábù àti ti Hágárì

7 Gébálì, Ámónì àti Ámálékì,Fílítísitíà, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tirẹ̀.

8 Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọnláti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Sela

9 Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánìbí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì,

10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórítí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù,àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà,

12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìníẸni pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà,bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14 Bí ìna ti i jó ìgbẹ́ ìgbóàti bí ọ̀wọ́ iná ti ń mú òkè-ńlá gbiná,

15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle Rẹ lépa wọnja wọn lójú pẹ̀lú ìjì Rẹ

16 fi ìtìjú kún ojú wọnkí àwọn ènìyàn báà lè ṣe àfẹ́rí orúkọ Rẹ àti kí o fí ìjì líle Rẹ dẹ́rùbà ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó ti wọn, kí wọ́n sì dáámù láéláékí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn

18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:pé ìwọ níkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.