1 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
2 Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́sẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.
3 Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:iṣẹ́ àwọn tí o yapa ni èmi kórìírawọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
4 Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ miÈmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.
5 Ẹnikẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnikejì Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,oun ní èmi yóò gé kúròẹni tí ó bá gbé ojú Rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,òun ní èmi kì yóò faradà fún.
6 Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtọ́ lórí ilẹ̀,kí wọn kí ó le máa bá mi gbé;ẹni tí o bá ń rìn ọ̀nà pípéòun ni yóò máa sìn mí.
7 Ẹni tí o bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,kò sí ẹni tí ń ṣèké ti yóò dúró ní iwájú mi.
8 Ní ojojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa lẹ́nu mọgbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;èmi yóò gé àwọn olùṣe búburúkúrò ní ìlú Olúwa.