Sáàmù 104 BMY

Ọlọ́run Aṣẹ̀dá Ayé Àti Ọ̀run

1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọlá ńláni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

2 Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní

3 Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi-àjà ìyẹ̀wù Rẹ.Ìwọ ti ó ṣe àwọ̀sánmọ̀ ni kẹ̀kẹ́-ogun Rẹìwọ tí ó ń rìn lórí àpá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

4 Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ Rẹ,Ọ̀wọ́ iná ni àwọn olùránsẹ́ Rẹ.

5 O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;tí a kò le è mi láéláé.

6 Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.

7 Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí Rẹ ni àwọn omi lọ,nípa ohùn àrá Rẹ ni wọ́n sálọ;

8 Wọn ṣàn kọjá lórí àwọn òkè,wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.

9 Ìwọ gbé òpin tí wọn kò le kọjá Rẹ̀ kálẹ̀;láéláé ní wọ́n kò ní lé bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.

10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn àfonífojì;tí ó ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11 Wọn fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omiàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òùngbẹ wọn.

12 Àwọn ẹyẹ ojú òfurufu tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omiwọn ń kọrin láàrin àwọn ẹ̀ka.

13 Ó bú omi rìn àwọn òkè láti iyẹ̀wù Rẹ̀ wá;a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èṣo iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹàti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lòkí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:

15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan,àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà.

16 Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára,Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.

17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.

18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.

19 Òsúpá jẹ àmì fún àkókòòòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀.

20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri.

21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọnwọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

22 Òòrùn ràn, wọn sì kó ara wọn jọ,wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ìhò wọn.

23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,àti sí làálàá Rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24 Iṣẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá a Rẹ.

25 Bẹ́ẹ̀ ni òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìṣàlẹ̀ láìníyeohun alàyè tí tóbi àti kékeré.

26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,àti Léfíàtanì, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú Rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò Rẹ̀.

28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,wọn yóò kó o jọ;nígbà tí ìwọ bá là ọwọ Rẹ̀,a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.

29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú Rẹ mọ́ara kò rọ̀ wọ́nnígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,wọn ó kú, wọn o sì padà sí erùpẹ̀.

30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí Rẹ,ní a dá wọn,ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ Rẹ̀

32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mí ní ń ó kọrin sí Olúwa:èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwaníwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.

34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ ọ lọ́rùnbí mo tí ń yọ̀ nínú Olúwa.

35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́sẹ̀ kúrò láyékí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.Yin Olúwa.