1 Ẹ kọrin túntún sí Olúwa,nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti apa mímọ́ Rẹ̀o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà Rẹ̀ di mímọ̀o fí òdodo Rẹ̀ han àwọn orílẹ̀ èdè.
3 Ó rántí ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì;gbogbo òpin ayé ni ó ti ríiṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,ẹ bu sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrèẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa Ọba.
7 Jẹ́ kí òkun kí o hó pẹ̀lú gbogboohun tí ó wà nínú Rẹ̀,Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀.
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó sápẹ́,ẹ jẹ́ kí òkè kí o kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú OlúwaNítorí tí yóò wá ṣè dájọ́ ayébẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodoàti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.