1 Asiwèrè wí nínú ọkàn Rẹ̀ pé,“kò sí Ọlọ́run.”Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;kò sí ẹnìkan tí ó ṣe rere.
2 Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wálórí àwọn ọmọ ènìyànbóyá ó le rí ẹni tí òye yé,ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
3 Gbogbo wọn sì ti yípadà,gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;kò sì sí ẹni tí ó ń ṣe rere,kò sí ẹnìkan.
4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní kọ́ ẹ̀kọ́:àwọn tí ó ń pa ènìyàn mí jẹ bí ẹníjẹ àkàràtí wọn kò sì ké pe Olúwa?
5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,nítorí Olúwa wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Ẹ̀yin olùṣe búburú ba èrò àwọn aláìní jẹ́,ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.
7 Ìgbàlà àwọn Ísírẹ́lì yóò ti Síónì wá!Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà,jẹ́ kí Jákọ́bù kí ó yọ̀, kí inú Ísírẹ́lì kí ó dùn!