1 Olúwa ń jọba, ọlá ńlá ní ó wọ̀ ní aṣọ;ọlá ńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọàti ìhàmọ́ra Rẹ̀ pẹ̀lú agbára.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì le è yí.
2 Ìjọba Rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;ìwọ wà títí ayé raye.
3 A ti gbé òkun sókè, Olúwa,òkun ti gbé ohùn wọn sókè;òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí Rẹ̀ dúró ṣinṣin;ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé Rẹ̀ lọ́sọ̀ọ́fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.