1 Ẹ fi ìyìn Olúwa.Ẹ kọrin titun sí Olúwa.Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́
2 Jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá ajẹ́ kí àwọn ọmọ Síónì kí ó níayọ̀ nínú ọba wọn.
3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ Rẹ̀jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
4 Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá Rẹ̀kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọnàti idà olójú méjì ní ọ́wọ́ wọn.
7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀ èdè,àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọnàti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ Rẹ̀ sí wọnèyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.