1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí bayí, àwọnẹni tí ó ràpadà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 Àwọn tí ó kó jọ láti ilẹ̀ wọ̀nnìláti ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn,láti àríwá àti òkun wá.
4 Wọn ń rìn káàkiri ni ihà ni ibi tí ọ̀nà kò sí,wọn kòrí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tíwọn ó máa gbé
5 Ebi ń pa wọn, òùngbẹ gbẹ wọn,ó sì Rẹ̀ ọkàn wọn nínú wọn.
6 Ní ìgbà náà wọn kígbe sókèsí Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlútí wọ́n lè máa gbé
8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ìyanu Rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
9 Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́runó sì fi ire fún ọkàn tí ebi ń pa.
10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,a dè wọ́n ni ìrora àti ní irin,
11 Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀Ọlọ́run, wọn kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá ògo,
12 Ó sì fi ìkorò Rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì sí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
15 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa Nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
16 Nítorí tí ó já ilẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ke irin wọ̀n nì ní agbede-méjì.
17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọnwọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹwọ́n sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọn kígbe sí Olúwa nínúìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdàámú wọn
20 Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ara wọn sí dáó sì yọ̀ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ̀.
23 Àwọn ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀ojú omi, wọn jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọn ri iṣẹ́ Olúwa,àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pasẹ, ó sì mú ìjì fẹ́tí ó gbé ríru Rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọn sìtún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:nítorí ìpọ́njú ọkan wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókèsí Olúwa nínú ìdàámú wọn,ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́-rọ́rọ́bẹ́ẹ̀ ní rirú omi Rẹ̀ duro jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárin àwọn ènìyànkí wọn kí ó sì yín ín ní ìjọ àwọn àgbà.
33 Ó sọ odò di ihà,àti orisun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eleso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú Rẹ̀;
35 O sọ ihà di adágún omi àtiilẹ̀ gbígbẹ di oríṣun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,wọ́n sì pìlẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàràtí yóò ma so èso tí ó dára;
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iyekò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dín kù.
39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù
40 Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ aládéó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìniraó mú ìdílé wọn pọ̀ bi agbo ẹran
42 Àwọn tí ó dúró sì ríi, inú wọn sì dùnṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu Rẹ̀ mọ́.
43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsí nǹkan wọ̀nyíkí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.