1 Ó ti fi ìpilẹ̀ Rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu ọ̀nà Síónìju gbogbo ibùgbé Jákọ́bù lọ
3 Ohun ológo ni a sọ nípa Rẹ,ilú Ọlọ́run;
4 “Èmi ó dárúkọ Rákábù àti Bábílónìláàrin àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:Fílístínì pẹ̀lú, àti Tirẹ, pẹ̀lú Kúṣìyóò sọ pé, èyí ni a bí ni Síónì.”
5 Nítòótọ́, tí Síónì ni a ó sọ,“Eléyìí àti eléyì í ni a bí nínú Rẹ̀,àti Ọlọ́run Ọ̀gá ògo ni yóò fìdí Rẹ̀ múlẹ̀.”
6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn Rẹ̀:“Eléyìí ni a bí ní Síónì.”
7 Àti àwọn olorin àti àwọn ti ń luohun èlò orin yóò wí pé,“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú Rẹ.”