1 Olúwa jọba;jẹ́ kí ayé kí ó wárìrìo jòkòó lórí ìtẹ́ kérúbùjẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2 Olúwa tóbi ní Síónì;o sì ga jù gbogbo orílẹ̀ èdè lọ.
3 Kí wọ́n sì yín orúkọ Rẹ̀ tí ó tóbití ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
4 Olúwa tóbi lọba, ó fẹ́ òdodo ó dá ìdọ́gba sílẹ̀;ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí o yẹ nínú Jákọ́bù.
5 Gbígbé ga ní Olúwa Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6 Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀wọ́n képe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,wọ́n pa ẹrí Rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lììwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedédé wọn jẹ wọ́n
9 Gbígbé ga ni Olúwa Ọlọ́run wakí a sìn ín ní òkè mímọ́ Rẹ̀nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.