Sáàmù 115 BMY

Ọlọ́run Nikan Ni Ògo Yẹ

1 Kí ṣe fún wa, Olúwa kì ṣe fún wá,ṣùgbọ́n fún orúkọ Rẹ̀ ní a fi ògo fún,fún àánú àti òtítọ́ Rẹ.

2 Torí kí ní àwọn aláìkọlà yóò ṣe sọ pé,níbo ni Ọlọ́run wa wà.

3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.

4 Òrìṣà fàdákà àti wúrà,iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn

5 Wọn ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọn ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.

6 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ràn:wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọ́n kò fi gbóòórùn

7 Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,wọ́n ní ẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.

8 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;gẹ́gẹ́ bẹ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.

9 Ìwọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn

10 Ẹ yin ilé Árónì, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn

11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:oun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Ísírẹ́lì;yóò bùkún ilé Árónì.

13 Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ síi síwájú àti síwájú,ìwọ àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwaẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti, Olúwa:ṣùgbọ́n ayé lo fi fún ọmọ ènìyàn.

17 Òkú kò le yìn Olúwa,tàbí ẹni tí o ti lọ sí ìṣàlẹ̀ ìdákẹ́jẹ́.

18 Ṣùgbọ́n àwa o fi ìbùkún fún Olúwaláti ìsinsìn yí lọ àti títí láéláé.Ẹ yin Olúwa.