1 Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún Rẹ̀,ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú Rẹ̀;
2 Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ Rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkunó sì gbée kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
3 Ta ni yóò gun òrí òkè Olúwa lọ?Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ Rẹ̀?
4 Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,ẹni tí kò gbé ọkàn Rẹ̀ sókè sí asántí kò sì búra èké.
5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà Rẹ̀.
6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀,tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, Ọlọ́run Jákọ́bù. Sela
7 Ẹ gbé orí yín sókè, Áà! Ẹ̀yin ọ̀nà;Kí á sì gbe yín sókè, áà! Ẹyin ilẹ̀kùn ayérayé!Kí ọba ògo le è wọlé.
8 Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan-an, tí o lágbára ní ogun.
9 Gbé orí yín sókè, áà! Ẹ̀yin ọ̀nà;Kí a sì gbé yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,Kí ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni ọba ogo náà? Olúwa àwọn ọmọ ogunÒun ni ọba ògo náà. Sela