Sáàmù 102 BMY

Àdúrà Olùpọ́njú Fún Ìrànlọ́wọ́

1 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ

2 Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ miní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.Dẹ etí Rẹ sí mi;nígbà tí mo bá pè, dámi lóhùn kíákíá.

3 Nítorí tí ọjọ́ rú bí èéfin;egungun mi sì jóná bí ààrò

4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.

5 Nítorí ohùn ìkérora mi,egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.

6 Èmi dà bí ẹyẹ igún ni ijù:èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.

7 Èmi dìde; èmí dàbí ẹyẹ lórí ilé.

8 Ní ọjọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta ológosẹ́ mi ń gàn mí;àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.

9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi si da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omíjé.

10 Nítorí ìbínú ríru Rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.

11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́èmi sì rọ bí koríko

12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;ìrántí Rẹ láti ìran dé ìran.

13 Ìwọ ó dìde ìwọ o sì ṣàánú fún Síónì,nítorí ìgbà àti ṣe ojú rere sí i;àkókò náà ti dé.

14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùnsí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ; wọ́n sì káànú ẹrùpẹ̀ Rẹ.

15 Àwọn ayé yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo Rẹ.

16 Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.

17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wáláti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé,

20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, lati túàwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”

21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ni Síónìàti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.

22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àtiìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀,ó gé ọjọ́ mi kúrú.

24 Èmi sì wí pé;“Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.

25 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọnwọn yóò sì di àpatì.

27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí ṣíbẹ̀,ọdún Rẹ kò sì ni òpin.

28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Rẹ̀ yóò dúró ní iwájú Rẹ pẹ́;a o sì fi ẹsẹ̀ irú ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú Rẹ.”