1 Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.
2 Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,mo wá Olúwa;ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú.
3 Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run,mo sì kẹ́dùn;mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela
4 Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn,mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
5 Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;
6 Mo rántí orin mi ní òru.Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀,ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ.
7 Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?Kí yóò ha ṣe ojú rere Rẹ̀ mọ́
8 Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ àti àánú Rẹ̀ tí kú lọ láéláé?Ìlérí Rẹ̀ ha kùnà títí ayé?
9 Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?Ní ìbínú Rẹ̀, ó ha sé ojú rere Rẹ̀ mọ́? Sela
10 Èmí wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi,pé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”.
11 Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa:bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.
12 Èmi ṣàṣárò lórí iṣẹ́ Rẹ gbogbopẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára Rẹ.
13 Ọlọ́run, Ọ̀nà Rẹ jẹ́ mímọ́.Ọlọ́run wo ní ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?
14 Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu;ìwọ fi agbára Rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.
15 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà,àwọn ọmọ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù. Sela
16 Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run,nígbà tí àwọn omi rí ọ,ẹ̀rù bà wọ́n,nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.
17 Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀,àwọ̀sánmọ̀ fí àrá dáhùn;ọfà Rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú
18 Àrá Rẹ̀ ni a gbọ ní ibi ìjì,ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé;ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.
19 Ìpa Rẹ̀ gba òkun, ọ̀nà Rẹ ń bẹ nínú òkun,Ọ̀nà la omi alágbára kọ́já ipa Rẹ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá,nítòótọ́ a kò rí ojú ẹṣẹ̀ Rẹ̀.
20 Ó tọ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹrannípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.