Sáàmù 38 BMY

Ẹ̀bẹ̀ Fún Ìwòsàn

1 OlúwaMá ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹ,bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mínínú ìrunú Rẹ̀.

2 Nítorí tí ọfà Rẹkàn mọ́ mi ṣinṣin,ọwọ́ Rẹ sìkì mí mọ́lẹ̀.

3 Kò sí ibi yíyè ní ara à minítorí ìbínú Rẹ;kò sí àlàáfíà nínú egungun minítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4 Nítorí àìṣedédé miti borí mi mọ́lẹ̀;wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgàtí ó wúwo jù fún mi:

5 Ọgbẹ́ mi ń rùnó sì díbàjẹ́nítorí òmùgọ̀ mi;

6 Èmi ń jòwèrè:orí mi tẹ̀ ba gidigidièmi ń sọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná ti ń jó nikò sì sí ibi yíyè ní ara mi,

8 Ara mi hù, a sì wó mi jégéjégé;mo ké rora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9 Olúwa,gbogbo a áyun mi ń bẹ níwájú Rẹ;ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10 Àyà mi ń mí hẹlẹ,agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni,ó ti lọ kúrò lára mi.

11 Àwọn ọ̀rẹ́ miàti àwọn ẹlẹgbẹ́ midúró lókèèrè rérékúrò níbi ìpọ́njú mi,àwọn alábàágbé é mi,dúró lókèèrè.

12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí midẹ okùn sílẹ̀ fún mi;àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lárań sọ̀rọ̀ nípa ìparun,wọ́n sì ń gbérò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi,èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

14 Ní tòótọ́,mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́ràn,àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa,ìwọ ni mo dúró dè;ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi,ẹni tí yóò dáhùn.

16 Nítorí tí mo gbàdúrà,“Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi”.

17 Nítorí tí mo ti ṣe tán láti ṣubú,ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá miláì ní ìdí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ókórìírá mi lọ́nà òdì.

20 Àwọn tí wọn ń fiibi san rere fún miàwọn ni ọ̀ta minítorí pé mò ń tọ ire lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀,ìwọ Olúwa!Ọlọ́run miMá ṣe jìnnà sí mi

22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́, Olúwa,Olùgbàlà mi.