Sáàmù 37 BMY

Olódodo Yóò Ṣe Rere: A Ó Gé Ènìyàn Búburú Lulẹ̀

1 Má ṣe ìkanra nítorí àwọnolùṣe búburú,kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlàra nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

2 nítorí pé wọn yóò gbẹbí koríko,wọn yóò sì Rẹ̀ dànùbí ewéko tútù

3 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,kí o sì máa ṣe rere;torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà,kí o sì gbádùn ààbò Rẹ̀

4 ṣe inú dídùn sí Olúwa;òun yóò sì fún ọ níìfẹ́ inú Rẹ̀.

5 Fi ọ̀nà Rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lée pẹ̀lú,òun yóò sì ṣe é.

6 Yóò sì mú kí òdodo Rẹ̀ jádebí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ,àti ìdájọ́ Rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú Olúwa,kí o sì fi sùúrù dúró dè é;má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọntí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,nítorí ọkùnrin náà ti múèrò búburú ṣẹ.

8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí,kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀.Má ṣe ṣe ìkanra,nítorí pé ó gbéni sí búburú pẹ̀lú.

9 Nítorí pé á ó gé àwọn ènìyànbúburú kúrò,Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwaàwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

10 Ṣíbẹ̀ nígbà díẹ̀ síi,,àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀wo ipò Rẹ̀,wọn kì yóò sí níbẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútùni yóò jogún ilẹ̀ náà,wọn yóò sì máa ṣe inú dídùnnínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

12 Ènìyàn búburú di rìkísí sí olóòtọ́,wọ́n sì pa ẹyín wọn keke sí wọn;

13 Ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rin-un síàwọn ènìyàn búburú,nítorí tí ó rí wí péọjọ́ wọn ń bọ̀.

14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,láti sọ talákà àti aláìní kalẹ̀,láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.

15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.

16 Ohun díẹ̀ tí olódodo nísàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú.

17 Nítorí pé a ó ṣẹ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn adúró ṣinṣin,àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;

19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé,àwọn ọ̀ta Olúwa yóò dà bíẹwà oko tútù;wọn fò lọ;bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21 Àwọn ènìyàn búburú yá,wọn kò sì san-án padà,ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa fi fún ni;

22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkúnni yóò jogún ilẹ̀ náà,àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wáláti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,o si ṣe inú dídùn sí ọ̀nà Rẹ̀;

24 Bí ó tilẹ̀ ṣubúa kì yóò ta á nù pátapáta,nítorí tí Olúwa di ọwọ́ Rẹ̀ mú.

25 Èmi ti wà ni èwe,báyìí èmí sì dàgbà;ṣíbẹ̀ èmi kò ì tíi rí kia kọ olódodo ṣílẹ̀,tàbí kí irú ọmọ Rẹ̀máa ṣagbe oúnjẹ.

26 Aláàánú ni òun nígbà gbogboa máa yá ni;a sì máa bùsí i fún ni.

27 Lọ kúrò nínú ibi,kí o sì máa ṣe rere;nígbà náà ni ìwọ gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.

28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ sílẹ̀.Àwọn olódodo ni a ó pamọ́títí ayérayé,ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburúní a ó ké kúrò.

29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

31 Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹní àyà wọn;àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́kì yóò sì dá a lẹ́bi,nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ Rẹ̀.

34 Dúró de Olúwa,kí o sì má a pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́,yóò sì gbé ọ lékèláti jogún ilẹ̀ náà:Nígbà tí a bágé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

35 Èmí ti rí ènìyàn búburútí n hu ìwà ìkà,ó sì fi ara Rẹ̀ gbilẹ̀ bíigi tútù ńlá.

36 Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan síi ó kọjá lọ,sì kíyèsí, kò sì sí mọ́;bi ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri,ṣùgbọ́n a kò le è ri.

37 Má a kíyèsí ẹni pípé,kí o sì wo adúró ṣinṣin,nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.

38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjání a ó parun papọ̀;ìran àwọn ènìyàn búburúní a ó gé kúrò.

39 Ìgbàlà àwọn adúró ṣinṣinwa láti ọ̀dọ̀ Olúwa:òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú

40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́yóò sì gbà wọ́n;yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú,yóò sì gbà wọ́n là,nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.