1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ Rẹ̀Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run Rẹ̀.
2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára Rẹ̀.Ẹ yìn ín fún títóbi Rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3 Ẹ fi ohùn ìpè, yìn ín.Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ínfi ohun èlò orin olokùn àti ìpè yìn ín
5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè.Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro
6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.