1 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìran ọ̀run,Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti agbára.
2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ Rẹ̀;sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3 Ohùn Olúwa ré àwọn omi kọjá;Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀.
4 Ohùn Olúwa ní agbára;ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5 Ohùn Olúwa fọ́ igi kédárì; Olúwa náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì.
6 Ó mú Lébánónì fo bí i ọmọ màlúù,àti Síríónì bí ọmọ àgbáǹréré.
7 Ohùn Olúwa ń yabí ọwọ́ iná mọ̀nà
8 Ohùn Olúwa ń mi ihà. Olúwa mi ihà Kádéṣì.
9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀rín bíó sì bọ́ igi igbó sí ìhòòhò.àti nínú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10 Olúwa jókòó, Ó sì jọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọbatítí láéláé.
11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn Rẹ̀;bùkún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.