Sáàmù 19 BMY

Ìṣẹ̀dá Àti Èrò Ń Fi Ògo Ọlọ́run Hàn

1 Àwọn òrun ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;Àwọ̀sánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀.

2 Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

3 Kò sí ohùn tàbí èdèníbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn

4 Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayéọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé,ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5 Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wáÒun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje.

6 Ìjáde lọ Rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wáàti àyíká Rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ Rẹ̀;kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore Rẹ̀.

7 Pípé ni òfin Olúwa,ó ń yí ọkàn padà.ẹ̀rí Olúwa dánilójú,ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8 Ìlànà Olúwa tọ̀nà,ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.àṣẹ Olúwa ní mímọ́,ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

9 Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,ó ń faradà títí láéláé.Ìdájọ́ Olúwa dájúòdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ,ju góòlù tí o dára jùlọ.wọ́n dùn ju oyin lọ,Àti ju afárá oyin lọ.

11 Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

12 Ta ni o lé mọ àṣìṣe Rẹ̀?Dáríjìn mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

13 Wẹ ìrànsẹ́ Rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;Má ṣe jẹ kí wọn kí ó jọba lórí mi.Nígbà náà ní èmí yóò dúró ṣinṣin,èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mikí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú Rẹ,Ìwọ Olúwa, àpáta mi.àti Olùdáǹdè mi.